5 Yóo dàbí ìgbà tí eniyan kórè ọkà lóko,tí ó kó ṣiiri ọkà kún apá.Tí àwọn kan tún wá ṣa ọkà yòókù,tí àwọn tí wọn kọ́ kórè ọkà gbàgbé ní àfonífojì Refaimu.
6 Àṣàkù yóo kù níbẹ̀,bí ìgbà tí eniyan gbọn igi olifi,yóo ku meji tabi mẹta péré ní góńgó orí igi,tabi bíi mẹrin tabi marun-un lórí ẹ̀ka igi.”OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.
7 Tó bá di ìgbà náà, àwọn eniyan yóo bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóo sì máa wo ojú Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8 Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari.
9 Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.
10 Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín;
11 wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọnsibẹsibẹ kò ní sí ìkórèní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn.