Aisaya 17:8-14 BM

8 Wọn kò ní náání pẹpẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn tẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní gbójúlé àwọn ère tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe, ìbáà jẹ́ oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari.

9 Tó bá di ìgbà náà, àwọn ìlú olódi ńláńlá wọn yóo dàbí àwọn ìlú tí àwọn ará Hifi ati àwọn ará Amori sá kúrò níbẹ̀, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbógun tì wọ́n; gbogbo rẹ̀ yóo di ahoro.

10 Nítorí pé ẹ ti gbàgbé Ọlọrun olùgbàlà yín,ẹ kò ranti Àpáta tí ó jẹ́ ààbò yín.Nítorí náà bí ẹ tilẹ̀ gbin igi dáradára tí ẹ̀ ń bọ ọ́,tí ẹ sì gbin òdòdó àjèjì tí ẹ̀ ń sìn ín;

11 wọn ìbáà hù lọ́jọ́ tí ẹ gbìn wọ́n,kí wọ́n yọ òdòdó ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ẹ lọ́ wọnsibẹsibẹ kò ní sí ìkórèní ọjọ́ ìbànújẹ́ ati ìrora tí kò lóògùn.

12 Ẹ gbọ́ ariwo ọ̀pọ̀ eniyan,wọ́n ń hó bí ìgbì òkun.Ẹ gbọ́ ìró àwọn orílẹ̀-èdèwọ́n ń hó bíi ríru omi òkun ńlá.

13 Ìró àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ti omi òkun ńláṣugbọn OLUWA yóo bá wọn wí wọn óo sì sá lọ.Wọn óo dàbí ìràwé tí afẹ́fẹ́ ń gbé lọ lórí òkè,ati bí eruku tí ìjì líle ń fẹ́ kiri.

14 Ìdágìrì yóo bá wọn ní ìrọ̀lẹ́,kí ilẹ̀ tó mọ́ wọn kò ní sí mọ́;bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n fogun kó wa,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù lọ.