15 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé:
16 ‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta?
17 Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá.
18 Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ.
19 N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’
20 “Ní ọjọ́ náà, n óo pe Eliakimu, iranṣẹ mi, ọmọ Hilikaya.
21 N óo gbé aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n óo sì dì í ní àmùrè rẹ; n óo gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́, yóo sì di baba fún àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda.