7 Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ!
8 Ta ni ó gbìmọ̀ irú èyí sí Tire,Ìlú tí ń fún àwọn ọba ìlú yòókù ládé?Tí ó jẹ́ pé kìkì ìjòyè ni àwọn oníṣòwò rẹ̀;gbogbo àwọn tí ń ta ọjà níbẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọlọ́lá ní gbogbo ayé.
9 OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó pinnu láti ba gbogbo iyì ògo jẹ,ati láti tẹ́ gbogbo àwọn ọlọ́lá ayé.
10 Ẹ̀yin ará Taṣiṣi,ẹ máa tàn ká orí ilẹ̀ yín títí ẹ ó fi kan odò Naili,kò sí èbúté tí yóo da yín dúró mọ́.
11 OLUWA ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkunÓ ti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì.Ó ti pàṣẹ nípa ilẹ̀ Kenaanipé kí wọ́n pa gbogbo ibi ààbò rẹ̀ run.
12 Ó ní, “Àríyá yín ti dópin,ẹ̀yin ọmọ Sidoni tí à ń ni lára.Ò báà dìde kí o lọ sí Kipru,ara kò ní rọ̀ ọ́ níbẹ̀.”
13 Ẹ wo ilẹ̀ àwọn ará Kalidea! Bí wọ́n ṣe wà bí aláìsí. Àwọn Asiria ti pinnu láti sọ Tire di ibùgbé àwọn ẹranko, wọ́n gbé àkàbà ogun ti odi rẹ̀. Wọ́n fogun kó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro.