13 Bẹ́ẹ̀ ní yóo rí ní ilẹ̀ ayé,láàrin àwọn orílẹ̀-èdèbí igi olifi tí a ti gbọn gbogbo èso rẹ̀ sílẹ̀,lẹ́yìn tí a ti kórè tán ninu ọgbà àjàrà.
14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ń kọrin ayọ̀,wọ́n ń yin OLUWA lógo láti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá.
15 Nítorí náà ẹ fi ògo fún OLUWA ní ìhà ìlà-oòrùn;ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ fògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.
16 Láti òpin ayé ni a ti ń gbọ́ ọpọlọpọ orin ìyìn,wọ́n ń fi ògo fún Olódodo.Ṣugbọn èmi sọ pé:“Mò ń rù, mò ń joro,mò ń joro, mo gbé!Nítorí pé àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,wọ́n ń dalẹ̀, wọ́n ń hùwà àgàbàgebè.”
17 Ẹ̀rù ati kòtò, ati tàkúté ń bẹ níwájú yín ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ ayé.
18 Ẹni tí ẹ̀rù bá bà tí ó sá,yóo já sinu kòtò,ẹni tí ó bá rá pálá jáde ninu kòtòyóo kó sinu tàkúté.Nítorí pé àwọn fèrèsé ojú ọ̀run ti ṣí,àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé sì mì tìtì.
19 Ayé ti fọ́, ayé ti fàya,ayé sì mì tìtì.