20 Ayé ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí,ó ń mì bí abà oko.Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́rùn,ó wó lulẹ̀, kò ní dìde mọ́.
21 Ní àkókò náà,OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ogun ọ̀run, lọ́run;ati àwọn ọba ayé, lórí ilẹ̀ ayé.
22 A óo gbá gbogbo wọn jọ pọ̀ sinu kòtò bí ẹlẹ́wọ̀n,wọn óo wà ní àtìmọ́lé ninu ẹ̀wọ̀n.Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, a óo fìyà jẹ wọ́n.
23 Òṣùpá yóo dààmú,ìtìjú yóo sì bá oòrùn.Nítorí OLUWA àwọn ọmọ-ogun yóo jọbalórí òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu.Yóo sì fi ògo rẹ̀ hànníwájú àwọn àgbààgbà wọn.