5 Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́,nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfinwọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànàwọ́n sì da majẹmu ayérayé.
6 Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ.Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀,eniyan díẹ̀ ni ó sì kù.
7 Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀.Igi èso àjàrà ń joró,gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn.
8 Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́,ariwo àwọn alárìíyá ti dópin.Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró.
9 Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún.
10 Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo,gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé.
11 Ariwo ta lóde nítorí kò sí ọtí waini,oòrùn ayọ̀ ti wọ̀;ayọ̀ di àwátì ní ilẹ̀ náà.