8 Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí
9 Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n?Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún?Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn,àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?
10 Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni,èyí òfin, tọ̀hún ìlànà.Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”
11 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lòláti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀.
12 Àwọn tí ó ti wí fún pé:Ìsinmi nìyí,ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi;ìtura nìyí.Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.
13 Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin,èyí òfin tọ̀hún ìlànà.Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìnkí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́;kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn,kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.
14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.