1 Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun!Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí.Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i,ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn.
2 Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun.Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀,bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi.
3 N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíkán óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́;n óo sì mọ òkítì sára odi yín.
4 Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀,láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀.A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú,a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀.
5 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn,ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.