Aisaya 29:3-9 BM

3 N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíkán óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́;n óo sì mọ òkítì sára odi yín.

4 Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀,láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀.A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú,a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀.

5 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn,ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

6 Lójijì, kíá,OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín,pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá;ati ààjà, ati ìjì líle,ati ahọ́n iná ajónirun.

7 Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà,yóo parẹ́ bí àlá,gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà,tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru.

8 Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun,tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun,tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlápé òun ń mu omiṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.

9 Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀,kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀.Ẹ fọ́ ara yín lójúkí ẹ sì di afọ́jú.Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí.Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle.