7 Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà,yóo parẹ́ bí àlá,gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà,tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru.
8 Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun,tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun,tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlápé òun ń mu omiṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun,bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.
9 Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀,kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀.Ẹ fọ́ ara yín lójúkí ẹ sì di afọ́jú.Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí.Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle.
10 Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín láraÓ ti di ẹ̀yin wolii lójú;ó ti bo orí ẹ̀yin aríran.
11 Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú,bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì.Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wétí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”Ó ní òun kò lè kà ánítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í.
12 Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wétí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”Ó ní òun kò mọ̀wé kà.
13 OLUWA ní,“Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi,ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí;ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi.Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.