17 Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan,gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-untítí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè.Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.”
18 Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín,ó ti ṣetán láti ṣàánú yín.Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́.Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA.
19 Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín.
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i.
21 Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.”
22 Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”
23 OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀.