1 Wò ó! Ọba kan yóo jẹ pẹlu òdodo,àwọn ìjòyè yóo sì máa ṣe àkóso pẹlu ẹ̀tọ́.
2 Olukuluku yóo dàbí ibi ààbò nígbà tí ẹ̀fúùfù bá ń fẹ́ati ibi ìsásí nígbà tí ìjì bá ń jàWọ́n óo dàbí odò ninu aṣálẹ̀,ati bí ìbòòji àpáta ńlá nílẹ̀ olóoru.
3 Àwọn tí wọ́n bá rí i kò ní dijú sí i,etí àwọn tí ó gbọ́ ọ kò ní di.
4 Àwọn tí kò ní àròjinlẹ̀ tẹ́lẹ̀ yóo ní òye,àwọn akólòlò yóo sì sọ̀rọ̀ ketekete.
5 A kò ní máa pe aláìgbọ́n ní ọlọ́lá mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní máa pe abàlújẹ́ ní eniyan pataki.
6 Nítorí pé aláìgbọ́n ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,ọkàn rẹ̀ sì ń pète ibi.Ó ń ro bí yóo ṣe hùwà ẹni tí kò mọ Ọlọrun,tí yóo sọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí OLUWA;tí yóo fi ẹni tí ebi ń pa sílẹ̀, láì fún un ní oúnjẹ,tí yóo sì fi omi du ẹni òùngbẹ ń gbẹ.
7 Kìkì ibi ni èrò inú àwọn eniyankeniyan.Wọn a máa pète ìkà,láti fi irọ́ pa àwọn talaka run,kì báà jẹ́ pé ẹjọ́ aláìní jàre.