1 Ní ọdún kẹrinla tí Ọba Hesekaya jọba, Senakeribu, ọba Asiria gbógun ti gbogbo ìlú olódi Juda, ó sì kó wọn.
2 Ọba Asiria rán Rabuṣake (olórí ogun rẹ̀), pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun; láti Lakiṣi sí ọba Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn dé ibi tí omi tí ń ṣàn wọ ìlú láti orí òkè tí ó wà ní ọ̀nà pápá alágbàfọ̀, wọ́n dúró níbẹ̀.
3 Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin jáde lọ bá wọn pẹlu Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin.
4 Rabuṣake bá sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé ọba ńlá Asiria ní kí ló gbójú lé rí?
5 Ó ní ṣé Hesekaya rò pé ọ̀rọ̀ ẹnu ni ọgbọ́n ati agbára tí wọ́n fi ń jagun ni; àbí ta ló gbójú lé tí ó fi ń ṣàìgbọràn sí òun?
6 Ó ní Ijipti tí Hesekaya gbára lé dàbí kí eniyan fi ìyè ṣe ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀, ìyè tí yóo dá, tí yóo sì gún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbára lé e lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ijipti jẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bá gbára lé e.
7 “Ó ní bí Hesekaya bá sì sọ fún òun pé, OLUWA Ọlọrun àwọn ni àwọn gbójú lé, òun óo bi í pé, ṣé kì í ṣe ojúbọ OLUWA náà ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ ni Hesekaya wó lulẹ̀ nígbà tí ó sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu pé, ẹyọ pẹpẹ kan ni kí wọ́n ti máa sin OLUWA?”