5 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Hesekaya ọba jíṣẹ́ fún Aisaya,
6 Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní:‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
7 Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀,yóo gbọ́ ìròyìn èké kan,yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.Nígbà tí ó bá dé ilén óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ”
8 Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun.
9 Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní:
10 “Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu.
11 Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni?