1 OLUWA ní,“Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró,àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí.Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e,yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè.
2 Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo,kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba.
3 Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú,yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́.
4 Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì,títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé.Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.”
5 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ;ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ,tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀;ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀;tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.
6 Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo,mo ti di ọwọ́ rẹ mú,mo sì pa ọ́ mọ́.Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé,mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;