12 Kí wọn fi ògo fún OLUWA,kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù.
13 OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin,ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun,ó kígbe, ó sì bú ramúramù.Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀.OLUWA ní:
14 “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo mára dúró.Ṣugbọn nisinsinyii, n óo kígbe,bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.N óo máa mí túpetúpe,n óo máa mí hẹlẹhẹlẹ.
15 N óo sọ àwọn òkè gíga ati àwọn kéékèèké di ilẹ̀,n óo mú kí gbogbo ewéko orí wọn gbẹ;n óo sọ àwọn odò di erékùṣù,n óo sì mú kí àwọn adágún omi gbẹ.
16 “N óo darí àwọn afọ́jú,n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí,n óo tọ́ wọn sọ́nà,ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí.N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn,n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú.N óo ṣe àwọn nǹkan,n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
17 A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò,ojú yóo sì tì wọ́n patapataàwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé:‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ”OLUWA ní:
18 “Gbọ́, ìwọ adití,sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran.