14 OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.
15 Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”
16 OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;
17 ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,wọ́n kú bí iná fìtílà.
18 ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.
19 Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titunó ti yọ jáde nisinsinyii,àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?N óo la ọ̀nà ninu aginjù,n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.
20 Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu: