16 OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;
17 ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,wọ́n kú bí iná fìtílà.
18 ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.
19 Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titunó ti yọ jáde nisinsinyii,àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?N óo la ọ̀nà ninu aginjù,n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.
20 Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:
21 Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,kí wọ́n lè kéde ògo mi.
22 “Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.