24 Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún.Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo.Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run,tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́,
25 èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán,tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀.Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n pomo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀.
26 Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi,tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ,èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé,‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé,‘A óo tún odi yín mọ,n óo sì tún yín kọ́.’
27 Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ!n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’
28 èmi tí mo sọ fún Kirusi pé:‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé:‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé,‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ”