Aisaya 45:14-20 BM

14 Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia,ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀,wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ,wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ.Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn,wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ.Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé,‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà,kò tún sí Ọlọrun mìíràn.Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”

15 Nítòótọ́,ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́,Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà.

16 Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì,ìdààmú yóo sì bá wọn.Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ èreyóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.

17 Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là,títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀.Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae.

18 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.)Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀,kò dá a ninu rúdurùdu,ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.

19 N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn.N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé:‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ.Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”

20 OLUWA ní:“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá,ẹ jọ súnmọ́ bí,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè.Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri,tí wọ́n sì ń gbadurasí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.