6 Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.
7 Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn,èmi ni mo dá alaafia ati àjálù:Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
8 Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run,kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde.Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu,èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀.
9 “Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé!Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà.Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé:‘Kí ni ò ń mọ?’Tabi kí ó sọ fún un pé,‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’
10 Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé:‘Irú kí ni o bí?’Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé:‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’Olúwarẹ̀ gbé!”
11 OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni,“Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni,tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi?
12 Èmi ni mo dá ayé,tí mo dá eniyan sórí rẹ̀.Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.