17 Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọnàwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn.
18 Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin.
19 Tí wọn ń wí pé:“Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá,kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i.Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”
20 Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé;tí wọn ń pe ire ní ibi!Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀,tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn!Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn,tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò.
21 Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé;tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀!
22 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé;tí wọ́n jẹ́ akikanjubí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn!
23 Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán;tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà.