1 Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́?Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn?
2 Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwéati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ.Ìrísí rẹ̀ kò dára,ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra,bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.
3 Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.
4 Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.