15 Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.Láti sọ ọkàn wọn jí.
16 Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,Èmi ni mo dá èémí ìyè.
17 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.
18 Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.
19 Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè,ati àwọn tí ó wà nítòsí;n óo sì wò wọ́n sàn.
20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun,nítorí òkun kò lè sinmi,omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.
21 Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.