1 Wò ó! Agbára OLUWA kò dínkù, tí ó fi lè gbani là,etí rẹ̀ kò di, tí kò fi ní gbọ́.
2 Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín,àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín,tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín.
3 Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́,ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́,ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú.
4 Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre,kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo.Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé.Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín,iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.
5 Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i.
6 Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ,eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora.Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín,ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.
7 Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi,ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀.Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín.Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun.