4 Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.
5 Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;
6 ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.
7 Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.
8 OLUWA ní,“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.
9 Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”
10 N óo máa yọ̀ ninu OLUWA,ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ;bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.