6 Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.”
7 N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́,n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀;nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa,ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli,tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.
8 OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.”Ó sì di Olùgbàlà wọn.
9 Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni,angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là.Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada.Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.
10 Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀:wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú.Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn,ó sì dojú ìjà kọ wọ́n.
11 Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́,ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀.Wọ́n bèèrè pé,ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà?Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀,tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?
12 Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose,tí ó pín òkun níyà níwájú wọn,kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae.