2 Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan;àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára,tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn,
3 tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú,níṣojú mi, nígbà gbogbo.Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà,wọ́n ń sun turari lórí bíríkì.
4 Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú,tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru;àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́.
5 Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí,nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.”Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi,bí iná tí ó ń jó lojoojumọ.
6 Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé,“N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san.
7 N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn,ati ti àwọn baba wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá,wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké.N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn.
8 “Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà,tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́,nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi,n kò ní pa gbogbo wọn run.