Aisaya 9:1-7 BM

1 Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé.

2 Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.

3 Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.

4 Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.

5 Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,iná yóo sì jó wọn run.

6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fún wa ní ọmọkunrin kan.Òun ni yóo jọba lórí wa.A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,Ọmọ-Aládé alaafia.

7 Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i,alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí