27 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu;ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada?Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣeta ni lè ká a lọ́wọ́ kò?
28 Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú:
29 Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini,ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín;nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò,ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà.
30 Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ,aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu.Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ,a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ.
31 Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè,kí ìwọ ìlú sì figbe ta.Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnìnítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá,kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọntí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn.
32 Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini?A óo sọ fún wọn pé,“OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”