1 Ó ṣe,ní òkè àwọn odò kan ní ilẹ̀ Sudaniibìkan wà tí àwọn ẹyẹ ti ń fò pẹ̀ẹ̀rẹ̀pẹ̀.
2 Ẹni tí ó rán ikọ̀ lọ sí òkè odò Naili,tí wọ́n fẹní ṣọkọ̀ ojú omi.Ẹ lọ kíá, ẹ̀yin iranṣẹ ayára-bí-àṣá,ẹ lọ sọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tí ara wọn ń dán,àwọn tí àwọn eniyan tí wọ́n súnmọ́ wọnati àwọn tí ó jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù.Orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sìí máa ń ṣẹgun ọ̀tá,àwọn tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá.
3 Gbogbo aráyé,ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè,ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.
4 Nítorí pé OLUWA sọ fún mi péòun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òunbí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan,ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè.
5 Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè,lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso,tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀,ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà,yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.
6 Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀,wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè,ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́.Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù.