4 Nítorí pé OLUWA sọ fún mi péòun óo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wolẹ̀ láti ibi ibùgbé òunbí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán gangan,ati bí ìkùukùu ninu ooru ìgbà ìkórè.
5 Nítorí pé kí ó tó di ìgbà ìkórè,lẹ́yìn tí ìtànná àjàrà bá ti rẹ̀, tí ó di èso,tí àjàrà bẹ̀rẹ̀ sí gbó, tí ó ń pọ́n bọ̀,ọ̀tá yóo ti dòjé bọ àwọn ìtàkùn àjàrà,yóo sì gé gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.
6 Gbogbo wọn yóo wà nílẹ̀,wọn yóo di ìjẹ fún àwọn ẹyẹ orí òkè,ati àwọn ẹranko inú ìgbẹ́.Àwọn ẹyẹ yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,àwọn ẹranko yóo fi wọ́n ṣe oúnjẹ jẹ ní ìgbà òtútù.
7 Ní àkókò náà, àwọn eniyan tí wọ́n ga, tí wọ́n sì ń dán,tí àwọn tí wọ́n súnmọ́ wọn, ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí wọn ń bẹ̀rù,orílẹ̀-èdè tí ó lágbára, tíí sì í máa ń ṣẹgun ọ̀tá,tí odò la ilẹ̀ wọn kọjá,wọn óo mú ẹ̀bùn wá fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,ní orí òkè Sioni, tí àwọn eniyan ń jọ́sìn ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.