1 OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi.N óo gbé ọ ga:n óo yin orúkọ rẹ.Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu,o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́,o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.
2 O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpào sì ti pa àwọn ìlú olódi run.O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú,ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́.
3 Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ.
4 Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka,ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro.Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò,ati ìbòòji ninu oòrùn.Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiribẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí;
5 ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀.O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́;bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́,bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu.