Aisaya 45:10-16 BM

10 Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé:‘Irú kí ni o bí?’Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé:‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’Olúwarẹ̀ gbé!”

11 OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni,“Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni,tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi?

12 Èmi ni mo dá ayé,tí mo dá eniyan sórí rẹ̀.Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.

13 Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi,n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́;òun ni yóo tún ìlú mi kọ́,yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀,láìgba owó ati láìwá èrè kan.”OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.

14 Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia,ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀,wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ,wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ.Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn,wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ.Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé,‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà,kò tún sí Ọlọrun mìíràn.Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”

15 Nítòótọ́,ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́,Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà.

16 Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì,ìdààmú yóo sì bá wọn.Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ èreyóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.