1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè,ọmọ bíbí inú Juda,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra,tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli,ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.
2 Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́,ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
3 OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde,àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,èmi ni mo sọ wọ́n jáde,tí mo sì fi wọ́n hàn.Lójijì mo ṣe wọ́n,nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ.
4 Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín,olóríkunkun sì ni yín pẹlu.
5 Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́:kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín,kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n,àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’