7 Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;ó ń retí ìwà òdodo,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.
8 Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé,tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀,títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́,kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà.
9 OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé.
10 Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá.Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.”
11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu,láti máa wá ọtí líle kiri,tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́,títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n!
12 Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn;ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun,wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.