6 Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run,kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀.Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín,ayé yóo gbó bí aṣọ,àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò;ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi,ìdáǹdè mi kò sì ní lópin.
7 “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi,ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan;ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.
8 Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ,kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú;ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae,ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”
9 Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára;jí bí ìgbà àtijọ́,bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́.Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ,tí o fi idà gún diragoni?
10 Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ,omi inú ọ̀gbun ńlá;tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà,kí àwọn tí o rà pada lè kọjá?
11 Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá,pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni.Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí,wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn;ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.
12 “Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu,ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú?Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko.