6 Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”
7 Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè,ẹni tí ń kéde alaafia,tí ń mú ìyìn rere bọ̀,tí sì ń kéde ìgbàlà,tí ń wí fún Sioni pé,“Ọlọrun rẹ jọba.”
8 Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè,gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀,nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i,tí OLUWA pada dé sí Sioni.
9 Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ra Jerusalẹmu pada.
10 OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.
11 Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀,ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan,ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA.
12 Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.