Aisaya 58:8-14 BM

8 “Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn bí ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́,ara yín yóo sì tètè yá.Òdodo yín yóo máa tàn níwájú yín.Ògo mi yóo ṣe ààbò lẹ́yìn yín.

9 Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,n óo sì da yín lóhùn.Ẹ óo kígbe pè mí,n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’“Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín,tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́,tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́.

10 Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ,ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn,òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán.

11 N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo,n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn;n óo mú kí egungun yín ó le,ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin,ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.

12 Ẹ óo tún odi yín tí ó ti wó lulẹ̀ mọ,ẹ óo sì gbé àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dìde.Àwọn eniyan yóo máa pè yín ní alátùn-únṣe ibi tí odi ti wó,alátùn-únṣe òpópónà àdúgbò fún gbígbé.

13 “Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi;bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú,tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo;bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín,tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín,tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ;

14 nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA,n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé,n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín.Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”