1 Ní àsìkò yìí ni Ámúráfélì ọba Ṣínárì, Áríókù ọba Élásárì, Kédóláómérì ọba Élámù àti Tídálì ọba Góímù
2 jáde lọ láti bá Bérà ọba Ṣódómù, Bírísà ọba Gòmórà, Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébérì ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí-ni nì Ṣóárì) jagun.
3 Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Ṣídímù (òkun iyọ̀).
4 Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kédóláómérì bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.
5 Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kédóláómérì àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n sígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ara Ráfáímù ní Aṣilerótì-Kánáímù, àwọn ará Ṣúsítù ni Ámù, àwọn ará Émímù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriátaímù,
6 àti àwọn ará Hórì ní orí-òkè wọ̀nnì Ṣéírì, títí ó fi dé Eli-Páránì ní etí ijù.
7 Wọ́n sì tún yípadà lọ sí Ẹn-Mísífátì (èyí yìí ni Kádésì), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámálékì, àti àwọn ará Ámórì tí ó tẹ̀dó sí Haṣaṣoní Támárì pẹ̀lú.