Jẹ́nẹ́sísì 5 BMY

Ìran Ádámù títí dé ìran Nóà

1 Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Ádámù.Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.

2 Ó dá wọn ní akọ àti abo, ó sì súre fún wọn. Nígbà tí ó dá wọn tan ó pè wọ́n ní “ènìyàn.”

3 Nígbà tí Ádámù di ẹni Àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣétì.

4 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Ṣétì, ó tún wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

5 Àpapọ̀ ọdún tí Ádámù gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.

6 Nígbà tí Ṣétì pé àrùnlélọ́gọ́rùn ún ọdún (105), ó bí Énọ́sì.

7 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Énọ́sì, ó sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

8 Àpapọ̀ ọdún Ṣẹ́tì sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.

9 Nígbà tí Énọ́sì di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kénánì.

10 Lẹ́yìn tí ó bí Kénánì, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-lé-mẹ́ẹ̀dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.

11 Àpapọ̀ ọdún Énọ́sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.

12 Nígbà tí Kénánì di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Máhálálélì:

13 Lẹ́yìn tí ó bí Máhálálélì, ó wà láàyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rín ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbínrin.

14 Àpapọ̀ ọjọ́ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú.

15 Nígbà tí Máhálálélì pé ọmọ àrúnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Járédì.

16 Máhálálélì sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Járédì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

17 Àpapọ̀ iye ọdún rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.

18 Nígbà tí Járédì pé ọmọ ọgọ́jọ-ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Énọ́kù.

19 Lẹ́yìn èyí, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) ó sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìnrin.

20 Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-méjìdínlógójì (962); ó sì kú.

21 Nígbà tí Énọ́kù pé ọmọ ọgọ́ta-ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Mètúsẹ́là.

22 Lẹ́yìn tí ó bí Mètúsẹ́là, Énọ́kù sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

23 Àpapọ̀ ọjọ́ Énọ́kù sì jẹ́ irínwó-dín-márùndínlógójì-ọdún (365).

24 Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn: a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ.

25 Nígbà tí Mètúsẹ́là pé igba-ó-dín-mẹ́talá ọdún (187) ní o bí Lámékì.

26 Lẹ́yìn èyí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-dín-méjìdínlógún ọdún (782), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

27 Àpapọ̀ ọdún Mètúsẹ́là jẹ́ ẹgbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.

28 Nígbà tí Lámékì pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan.

29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn-ún.”

30 Lẹ́yìn tí ó bí Nóà, Lámékì gbé fún ẹgbẹ̀ta-ó-dín-márùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

31 Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-dín-mẹ́talélógún (777), ó sì kú.

32 Lẹ́yìn tí Nóà pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣémù, Ámù àti Jáfétì.