Jẹ́nẹ́sísì 30 BMY

1 Nígbà tí Rákélì rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Líà, arabìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jákọ́bù pé, “Fún mi lọmọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú”

2 Inú sì bí Jákọ́bù sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Olúwa, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?”

3 Nígbà náà ni Rákélì wí pé, “Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin mi nìyìí, bá a lòpọ̀, kí ó ba à le bí ọmọ fún mi, kí èmi si le è tipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”

4 Báyìí ni Rákélì fi Bílíhà fún Jákọ́bù ní aya, ó sì bá a lò pọ̀.

5 Bílíhà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jákọ́bù.

6 Rákélì sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohún ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.

7 Bílíhà, ọmọ ọ̀dọ̀ Rákélì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kéjì fún Jákọ́bù.

8 Nígbà náà ni Rákélì wí pé, “Mo ti bá ẹ̀gbọ́n mi ja ìjàkadì ńlá, èmi sì ti borí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Náfítalì.

9 Nígbà tí Líà sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Ṣílípà fún Jákọ́bù bí aya.

10 Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ Líà sì bí ọmọkùnrin kan fún Jákọ́bù

11 Nígbà náà ni Líà wí pé, “Orí rere ni èyi!” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Gádì.

12 Ṣílípà ọmọ ọ̀dọ̀ Líà sì tún bí ọmọkùnrin kejì.

13 Nígbà náà ni Líà wí pé, “Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Áṣérì.

14 Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Rúbẹ́nì jáde lọ sí oko, ó sì rí ọ̀gbòn mádírákì, ó sì mu un tọ Líà ìyá rẹ̀ wá. Rákélì sì wí fún Líà pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ara mádírákì tí ọmọ rẹ mú wá.”

15 Ṣùgbọ́n Líà da lóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba mádírákì ọmọ mi pẹ̀lú?”Rákélì sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí mádírákì ọmọ rẹ.”

16 Nítorí náà, nígbà tí Jákọ́bù ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Líà jáde lọ pàde rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi mánídárákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jákọ́bù sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà.

17 Ọlọ́run sì gbọ́ tí Líà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kárùn-un fún Jákọ́bù.

18 Nígbà náà ni Líà wí pé, “Ọlọ́run ti ṣẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákárì.

19 Líà sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jákọ́bù.

20 Nígbà náà ni Líà tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣébúlúnì.

21 Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.

22 Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rákélì, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì sí i ní inú.

23 Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ó sì wí pé, “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò.”

24 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Jóṣẹ́fù, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún-un fún mi.”

Agbo Ẹran Jákọ́bù Pọ̀ Sí i

25 Lẹ́yìn tí Rákélì ti bí Jóṣẹ́fù, Jákọ́bù wí fún Lábánì pé, “Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá.

26 Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀na mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó”

27 Ṣùgbọ́n Lábánì wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ.

28 Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án.”

29 Jákọ́bù sì wí fún un pé, “Ìwọ sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ àti bí ẹran ọ̀sìn rẹ ti pọ̀ si lábẹ́ ìtọ́jú mi.

30 Ìwọ̀nba díẹ̀ sá à ni o ní kí èmi tó dé, ó sì ti pọ̀ sí i gidigidi, Olúwa sì ti bùkún ọ nínú gbogbo èyí tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà wo ní èmi yóò pèsè fún ìdílé tèmi.”

31 Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?”Jákọ́bù dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn.

32 Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi.

33 Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó-iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí i gbé.”

34 Lábánì sì dáhùn pé, “Mo faramọ́ ọn, ṣe bí ìwọ ti wí”

35 Ní ọjọ́ náà gan-an ni Lábánì kó gbogbo ewúrẹ̀ tí ó lámì tàbí ilà (àti akọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgbò dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

36 Ibi tí Lábánì àti Jákọ́bù sì wà sí ara wọn, sì tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jákọ́bù sì ń tọ́jú agbo ẹran Lábánì tí ó kù.

37 Nígbà náà ni Jákọ́bù gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi pópílárì, àti álímọ́ńdì àti igi Píléénì. Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ.

38 Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi

39 Tí àwọn ẹran sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára.

40 Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Lábánì, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jákọ́bù dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo-ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Lábánì.

41 Nígbà kígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jákọ́bù yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mumi.

42 Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé wọn kò lera, kò ní fi àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀. Nítorí náà, àwọn tí kò lera ń jẹ́ ti Lábánì, nígbà tí àwọn tí ó lera ń jẹ́ ti Jákọ́bù.

43 Nítorí ìdí èyí, Jákọ́bù di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo-ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́-kùnrin, ìránṣẹ́-bìnrin pẹ̀lú ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.