1 Jósẹ́fù kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sunkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀.
2 Ó sì sunkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Éjíbítì gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Fáráò pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀.
3 Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Jósẹ́fù! Ṣe baba mi sì wà láàyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀.
4 Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Éjíbítì!
5 Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín.
6 Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀ ṣíwájú fún ọdún márùn ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú ọmọ yín sí fún-un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là.
8 “Nítorí náà kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ìhín bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba (Olùdámọ̀ràn) fún Fáráò, alákóso fún gbogbo ilé Fáráò àti alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.
9 Nísinsìn yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Jósẹ́fù ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe àkóso fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara.
10 Ìwọ yóò gbé ní agbégbé Gósénì, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi-ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní.
11 Èmi yóò pèṣè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó sì ku ọdún márùn ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má baà di aláìní.
12 “Ẹ̀yin fúnra yín àti Bẹ́ńjámínì arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Jósẹ́fù ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀.
13 Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Éjíbítì àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.”
14 Nígbà náà ni ó dì mọ́ Bẹ́ńjámínì arákùnrin rẹ̀, ó sì sunkún, Bẹ́ńjámínì náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú.
15 Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sunkún sí wọn lára. Lẹ́yìn èyí, Jósẹ́fù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀.
16 Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Fáráò pé àwọn arákùnrin Jósẹ́fù dé, inú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn.
17 Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kénánì,
18 kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá. Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí.’
19 “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí: Ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Éjíbítì fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá.
20 Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun-ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Éjíbítì yóò jẹ́ tiyín.’ ”
21 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí. Jósẹ́fù fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Fáráò ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìn-àjò wọn pẹ́lú.
22 Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún ẹyọ owó (300) idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn ún.
23 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Éjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ.
24 Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!”
25 Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn ní ilẹ̀ Kénánì.
26 Wọn wí fún un pé, “Jósẹ́fù sì wà láàyè! Kódà òun ni alákòóṣo ilẹ̀ Éjíbítì” Ẹnu ya Jákọ́bù, kò sì gbà wọ́n gbọ́
27 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jákọ́bù, baba wọn ṣọ.
28 Ísírẹ́lì sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Jósẹ́fù ọmọ mi wà láàyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”