1 Ádámù sì bá aya rẹ̀ Éfà lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Káínì. Ó wí pé, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa ni mo bí ọmọkùnrin.”
2 Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Ábélì.Ábélì jẹ́ darandaran, Káínì sì jẹ́ àgbẹ̀.
3 Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Káínì mú ọrẹ wá fún Olúwa nínú èṣo ilẹ̀ rẹ̀.
4 Ṣùgbọ́n Ábélì mú ẹran tí ó sanra wá fún Olúwa nínú àkọ́bí ẹran-ọ̀sìn rẹ̀. Olúwa sì fi ojú rere wo Ábélì àti ọrẹ rẹ̀,
5 ṣùgbọ́n Olúwa kò fi ojú rere wo Káínì àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Káínì gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro.
6 Nígbà náà ni Olúwa bi Káínì pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro?
7 Bí ìwọ ba ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.”
8 Káínì wí fún Ábélì arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Káínì da ojú ìjà kọ Ábélì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.
9 Nígbà náà ni Olúwa béèrè lọ́wọ́ Káínì pé, “Níbo ni Ábélì arákùnrin rẹ wà?”Ó sì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ibi tí ó wà, èmí ha ń ṣe olùṣọ́ arákùnrin mi bí?”
10 Olúwa wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá.
11 Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ.
12 Bí ìwọ bá ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò so èṣo rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.”
13 Káínì wí fún Olúwa pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ.
14 Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.”
15 Ṣùgbọ́n, Olúwa wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Káínì, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi àmì sí ara Káínì, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí má ba pa á.
16 Káínì sì kúrò níwájú Ọlọ́run, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nódì ní ìhà ìlà oòrùn Édẹ́nì.
17 Káínì sì bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Énókù. Káínì sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Énókù sọ ìlú náà.
18 Énókù sì bí Írádì, Írádì sì ni baba Méhújáélì, Méhújáélì sì bí Métúsáélì, Métúsáélì sì ni baba Lámékì.
19 Lámékì sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkíní ni Ádà, àti orúkọ èkejì ni Ṣílà.
20 Ádà sì bí Jábálì: òun ni baba irú àwọn tí ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran-ọ̀sìn.
21 Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Júbálì, òun ni baba irú àwọn tí ń tẹ dùùrù tí wọ́n sì ń fọn fèrè.
22 Ṣílà náà sì bí ọmọkùnrin tí ń jẹ́ Tubali-Káínì, tí ó ń rọ oríṣìíríṣìí ohun èlò láti ara idẹ àti irin. Arábìnrin Tubali-Káínì ni Náámà.
23 Lámékì wí fún àwọn aya rẹ̀,“Ádà àti Ṣílà, ẹ tẹ́tí sí mi;ẹ̀yin aya Lámékì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí,ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára.
24 Bí a ó bá gbẹ̀san Káínì ní ìgbà méje,ǹjẹ́ kí a gba ti Lámékì nígbà àádọ́rin-lé-méje.”
25 Ádámù sì tún bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣẹ́tì, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Ábélì tí Káínì pa.”
26 Ṣẹ́tì náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́sì.Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ Olúwa.