1 Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Ábúráhámù, Ísáákì sì lọ sọ́dọ̀ Ábímélékì ọba àwọn Fílístínì ni Gérárì.
2 Olúwa sì fi ara han Ísáákì, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì: Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi sọ fún ọ.
3 Dúró ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún ọ. Nítorí ìwọ àti irú ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Ábúráhámù baba rẹ mulẹ̀.
4 Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n ó sì fún wọn ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó sì bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé,
5 nítorí pé Ábúráhámù gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.”
6 Nítorí náà Ísáákì dúró ní Gérárì.
7 Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà béèrè bí t'òun àti ti Rèbékà ti jẹ́, ó dáhùn pé, arábìnrin òun ní í ṣe nítorí pé ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ wí pé aya òun ni; ó ń rò ó wí pé wọ́n le pa òun nítorí Rèbékà, nítorí ti Rèbékà lẹ́wà púpọ̀.
8 Nígbà tí Ísáákì sì ti wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, Ábímélékì ọba Fílístínì yọjú lójú fèrèsé, ó sì rí Ísáákì ń bá Rèbékà aya rẹ̀ tage.
9 Nígbà náà ni Ábímélékì ránṣẹ́ pe Ísáákì ó sì wí fun pé, “Nítòótọ́, aya rẹ ni obìnrin yìí í ṣe, èéṣe tí o fi pè é ní arábìnrin rẹ?”Ísáákì sì fèsì pé, “Nítorí mo rò pé mo le pàdánù ẹ̀mí mi nítorí rẹ̀.”
10 Nígbà náà ni Ábímélékì dáhùn pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá ti bá a lò pọ̀ ńkọ́? Ìwọ ìbá wá mú ẹ̀bi wá sórí wa.”
11 Nígbà náà ni Ábímélékì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú”
12 Ní ọdún náà, Ísáákì gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀rún ni ọdún kan náà nítorí Ọlọ́run bùkún un.
13 Ó sì di ọlọ́rọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ọlọ́rọ̀ gidigidi.
14 Ó ní ọ̀pọ̀lopọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Fílístínì ń ṣe ìlara rẹ̀.
15 Nítorí náà àwọn ará Fílístínì ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù baba rẹ̀ ti gbẹ́.
16 Nígbà náà ni Ábímélékì wí fún Ísáákì pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”
17 Ísáákì sì sí kúrò níbẹ̀, ó sì pàgọ́ sí àfonífojì Gérárì ó sì ń gbé ibẹ̀.
18 Ísáákì sì ṣe àtúngbẹ́ àwọn kànga tí baba rẹ̀ ti gbẹ́ nígbà ayé rẹ̀, èyí tí àwọn Fílístínì ti dí lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ó sì fún wọn lórúkọ tí baba rẹ̀ ti sọ wọ́n tẹ́lẹ̀.
19 Àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì sì gbẹ́ kànga ní àfonífojì náà, wọ́n kan ìsun omi níbẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gérárì ń bá àwọn darandaran Ísáákì jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni ín. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Éṣékì, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà.
21 Àwọn ìránṣẹ́ Isáákì tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣìtínà (kànga àtakò).
22 Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì já sí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì, ó wí pé, “Nísinsìnyìí, Olúwa ti fi àyè gbà wá, a ó sí i gbilẹ̀ sì ni ilẹ̀ náà.”
23 Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Bíáṣébà.
24 Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fara hàn-án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi.”
25 Ísáákì sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan ṣíbẹ̀.
26 Nígbà náà ni Ábímélékì tọ̀ ọ́ wá láti Gérárì, àti Áhúsátì, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fíkólì, olórí ogun rẹ̀.
27 Ísáákì sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yin?”
28 Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrin àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn
29 pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láì ṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.”
30 Ísáákì sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu.
31 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Ísáákì sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà.
32 Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn ìránṣẹ́ Ísáákì wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́.
33 Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣébà (kànga májẹ̀mu), títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Bíáṣébà.
34 Nígbà tí Ísọ̀ pé ọmọ ogójì ọdún (40) ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Júdíìtì, ọmọ Béérì, ará Hítì, ó sì tún fẹ́ Báṣémátì, ọmọ Élónì ará Hítì.
35 Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Ísáákì àti Rèbékà.