Jẹ́nẹ́sísì 39 BMY

Jósẹ́fù àti Aya Pọ́tífà

1 Nígbà tí wọ́n mú Jósẹ́fù dé Éjíbítì, Pótífà, ará Éjíbítì tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò. Òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Fáráò. Ó ra Jósẹ́fù lọ́wọ́ àwọn ará Íṣímáẹ́lì tí wọ́n mú-un lọ ṣíbẹ̀.

2 Olúwa sì wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì bùkún-un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Éjíbítì.

3 Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.

4 Jósẹ́fù sì rí ojúrere Pọ́tífà, ó sì di asojú rẹ̀, Pọ́tífà fi Jósẹ́fù ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

5 Láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun-ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún-un nítorí Jósẹ́fù. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Pọ́tífà ní, nílé àti lóko.

6 Ó sì fi Jósẹ́fù ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù ṣe àkóṣo ilé e rẹ̀.Josẹ́fù sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀,

7 lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Jósẹ́fù, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lò pọ̀!”

8 Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́.

9 Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”

10 Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Jósẹ́fù, Jósẹ́fù kọ̀ láti bá a lò pọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

11 Ní ọjọ́ kan, Jósẹ́fù lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí.

12 Ó sì di aṣọ Jósẹ́fù mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lò pọ̀!” Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.

13 Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde,

14 ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Ébérù kan wọlé tọ̀ wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lò pọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe.

15 Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sokè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”

16 Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé.

17 Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará a Ébérù tí o rà wálé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lò pọ̀.

18 Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”

19 Nígbà tí Pọ́tífà gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi.

20 Ó sì ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jóṣẹ́fù wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀,

21 Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà).

22 Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Jọ́ṣẹfù ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń se níbẹ̀.

23 Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Jósẹ́fù, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ lé.