Jẹ́nẹ́sísì 37 BMY

Àlá Jósẹ́fù

1 Jákọ́bù sì gbé ilẹ̀ Kénánì ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.

2 Èyí ni àwọn ìtàn Jákọ́bù.Nígbà tí Jósẹ́fù di ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún (17), ó ń sọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwon ọmọ Bílíhà àti Sílípà aya baba rẹ̀ Jósẹ́fù sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

3 Jákọ́bù sì fẹ́ràn Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tó kù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un.

4 Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kóríra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrin wọn.

5 Jósẹ́fù lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórira rẹ̀ sí i.

6 O wí fún wọn pé “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá:

7 Sáà wò ó, àwa ń yí ìdì ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìdì ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìdì ọkà tiyín sì dòòyì yí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

8 Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbérò àti jọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa ní tòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.

9 O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń forí balẹ̀ fún mi.”

10 Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá forí bálẹ̀ níwájú rẹ ni?”

11 Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣugbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.

Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù tà á

12 Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣékémù.

13 Ísírẹ́lì sì wí fún Jósẹ́fù pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákunrin rẹ ń da ẹran ní Ṣékémù, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.”Jósẹ́fù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

14 O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Jósẹ́fù lọ láti àfonífojì Ébúrónì.Nígbà tí Jósẹ́fù dé Ṣékémù,

15 Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”

16 Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”

17 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dótanì.’ ”Jósẹ́fù sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dótanì.

18 Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

19 “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn.

20 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”

21 Nígbà tí Rúbẹ́nì gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀,

22 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn an, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láàyè nínú asálẹ̀ níbí.” Rúbẹ́nì sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.

23 Nítorí náà, nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀—

24 wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú un rẹ̀.

25 Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Íṣímáélì tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gílíádì. Ràkunmí wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjíá, wọ́n ń lọ sí Éjíbítì.

26 Júdà wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kín ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi?

27 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Íṣímáélì, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì faramọ́ ohun tí ó sọ.

28 Nítorí náà, nigbà tí àwọn onísòwò ara Mídíánì ń kọjá, àwọn arákùnrin Jósẹ́fù fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Íṣímáélì ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Jósẹ́fù lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì

29 Nígbà tí Rúbẹ́nì padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Jósẹ́fù kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́.

30 Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdé-kùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?”

31 Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Jósẹ́fù, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà.

32 Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà pada sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.”

33 Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Áà! aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àníàní, ó ti fa Jósẹ́fù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

34 Nígbà náà ni Jákọ́bù fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì sọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́

35 Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí iṣà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Jósẹ́fù sì sunkún fún un.

36 Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, àwọn ará Mídíánì ta Jósẹ́fù ní Éjíbítì fún Pótífà, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò, tí í ṣe olórí ẹ̀sọ́.