Jẹ́nẹ́sísì 23 BMY

Ikú Ṣárà

1 Ṣárà sì pé ọmọ ọdún mẹ́tà-dín-láàádóje (127)

2 ó sì kú ní Kíríátì-Áríbà (ìyẹn ní Hébúrónì) ní ilẹ̀ Kénánì, Ábúráhámù lọ láti sọ̀fọ̀ àti láti sunkún nítorí Ṣárà.

3 Ábúráhámù sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hítì wí pé,

4 “Iwo jẹ́ àjèjì àti àlejò láàrin yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”

5 Àwọn ará Hítì dá a lóhùn pé,

6 “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrin wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dárajù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dùn ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”

7 Nígbà náà ni Ábúráhámù dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà-àwọn ará Hítì.

8 Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì,

9 kí ó ta ihò àpáta Mákípélà tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrin yín.”

10 Éfúrónì ará Hítì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Ábúráhámù lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú,

11 pé, “Rárá, Olúwa mi, Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ ṣíbẹ̀.”

12 Ábúráhámù sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà,

13 Ó sì wí fún Éfúrónì lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi ṣíbẹ̀.”

14 Éfúrónì sì dá Ábúráhámù lóhùn pé,

15 “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irínwó (400) òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrin àwa méjèèjì? Ṣáà sin òkú ù rẹ.”

16 Ábúráhámù sì gba ohun tí Éfúróni wí, ó sì wọn iye owó fàdákà náà lójú gbogbo ènìyàn: irínwó owó idẹ fàdákà gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n oníṣòwò ayé ìgbà náà.

17 Báyìí ni ilẹ̀ Éfúrónì tí ó wà ni Mákípélà nítòòsí Mámúrè-ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú,

18 bí ohun-ìní fún Ábúráhámù níwájú gbogbo ará Hétì tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà.

19 Lẹ́yìn náà ni Ábúráhámù sin aya rẹ̀ Sárà sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Mákípélà nítòòsí Mámúrè (tí í ṣe Ébúrónì) ní ilẹ̀ Kénánì.

20 Ilẹ̀ náà àti ihò-àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hítì fi fún Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.