Jẹ́nẹ́sísì 43 BMY

Ìrìnàjò ẹ̀ẹ̀kejì lọ sí Éjíbítì

1 Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.

2 Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Éjíbítì tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ́ díẹ̀ si wá fún wa.”

3 Ṣùgbọ́n Júdà wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’.

4 Tí ìwọ yóò bá rán Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ.

5 Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ”

6 Ísírẹ́lì béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”

7 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe bàbá yín sì wà láàyè?’ Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?: A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”

8 Júdà sì wí fún Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú.

9 Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mu un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ.

10 Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ì bá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”

11 Nígbà náà ni Ísírẹ́lì baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà-ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjíá, èso Písítakíò àti eso álímíndì

12 ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló sèèsì fi ṣíbẹ̀.

13 Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ.

14 Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọhun-un àti Bẹ́ńjámínì padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó sọ̀fọ̀ wọn náà ni.”

15 Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Bẹ́ńjámínì, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Jóṣẹ́fù.

16 Nígbà tí Jóṣẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì se àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.”

17 Ọkùnrin náà sì ṣe bí Jósẹ́fù ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù.

18 Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”

19 Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Jósẹ́fù, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ilé náà.

20 Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá” Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí a wá ra oúnjẹ.

21 Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu-un padà wá pẹ̀lú wa.

22 A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.

23 Ó dáhùn pé, “Ó dára, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìsúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Símónì jáde tọ̀ wọ́n wá.

24 Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú.

25 Wọ́n pèṣè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Jósẹ́fù di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán.

26 Nígbà tí Jósẹ́fù dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún-un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

27 Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láàyè?”

28 Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láàyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un.

29 Bí ó ti wo yíká tí ó sì rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan-an. Ó béèrè lọ̀wọ̀ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó sàánú fún ọ, ọmọ mi”

30 Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Jósẹ́fù yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sunkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sunkún níbẹ̀.

31 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun.

32 Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fun-un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Éjíbítì tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Éjíbítì kò le bá ará Ébérù jẹun nítorí ìríra pátapáta ló jẹ́ fún àwọn Éjíbítì.

33 A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátapáta dé orí èyí tí ó kéré pátapáta, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu.

34 A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Jósẹ́fù. Oúnjẹ Bẹ́ńjámínì sì tó ìlọ́po márùn-ùn ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láì sí ìdíwọ́.